
Add to My Library
Ibi kika yi so fun wa wipe Olorun ti fun wa ni iye ainipekun ati wipe iye wa ninu Omo Re Jesu Kristi. Ibeere ti o farahan ni wipe bawo ni a se lee ni Omo Olorun?
Gegebi bii iwe Romu ori karun ese ikejo, Olorun fi ife Re han si wa nipa iku Omo Re. Kini idi ti Jesu se ni lati ku fun wa? Nitori iwe mimo so wipe gbogbo eniyan ni o je elese. Lati da “ese” je lati kuna . Bibeli so wipe “gbogbo eniyan lo sa ti se, ti nwon si ti kuna ogo Olorun” (Romu 3:23) Ni ona miran ewe, awon ese wa muwa yapa si Olorun ti o je pipe ninu iwa mimo (ododo ati idajo) ati wipe Olorun gbodo da eniyan elese lejo.

Iwe mimo ko wa wipe ko si iwa rere eniyan, ise ti eniyan, iwa omoluwabi, tabi ise isin kan ko le je ki aje itewogba lodo Olorun tabi mu ki enikeni de orun. Omoluwabi eniyan, elesin eniyan, ati eniti ko mo ati alaimo ni won wa ninu oko kan. Gbogbo won ni o kuna odod Olorun ti o pe. Lehin ti Aposteli Paulu ti soro lori, eniyan alaimo, omoluwabi eniyan elesin eniyan, ni Romu 1: 18-3:8, Aposteli Paulu jeki o di mimo wipe awon Ju ati awon ara Hellene ni nwon wa labe ese, wipe, “ko si eniti ise olododo, ko si enikan” (Romu 3:9-10). Afikun eyi ni awon ikede ese oro iwe mimo wonyi:
Ko si iwa rere eniyan ti o lee dara bi ti Olorun. Olorun pe ninu ododo. Nitori eyi, Habakuku 1:13Olorun ko le ni idapo pelu enikekeni ti kop e ninu ododo. Ki a ba lee je itewogba lati odo Olorun, a gbodo dara bi ti Olorun gann. Niwaju Olorun, a wa ni ihooho, ainiagbara, ati alaini ireti ninu ara wa. Ko si iye iwa omoluwabi ti o lee muwa de orun tabi fun wa ni iye ayeraye. Ki wa ni ona abayo?
Kii se wipe Olorun pe nipa mimo nikan (eni nipa ise ododo wa, a kole kunju osuwon mimo Re ) sugbon O pe nipa ife, okun fun oore-ofe ati aanu. Nitori ife ati oore-ofe Re, Ko fi wa sile laini ireti ati ona bayo.
Eyi ni irohin ayo ti Bibeli-ise iranse ihinrere Eyi ni ise iranse ebun Omo Re eniti o di eniyan (Olorun ninu eniyan), eni ti o gbe igbe aye alailese, ti o si ku lori igi agbelebu tori ese wa, ti a si ji dide kuro ninu ipo oku ti o si fihan wipe Omo Olorun Ni ni tooto ati wipe On ni aropo fun wa.
Eniti a pinnu re lati je pelu agbara omo Olorun, gege bi Emi mimo, nipa ajinde kuro ninu oku, ani Jesu Kristi Oluwa wa.

Nitori ohun ti Jesu Kristi se fun wa lori agbelebu, Bibeli so wipe “Eniti o ba ni Omo ni iye.” A lee gba Omo, Jesu Kristi, gegebi Olugbala nipa igbagbo ti ara wa, nipa gbigbekele eniti Kristi i je ati iku Re fun awon ese wa.
Eyi tumo si wipe eni kookan gbodo to Olorun wa ni ona kanan: (1) gege bi elese ti o mo ara ni elese., (2) mo wipe ko si ise eniyan ti o yori si igbala, ati (3) gbekele Kristi patapata nipa igbagbo nikan fun igbala wa.
Bi iwo setan lati gba ati gbekele Kristi gegebi Olugbala re, o lee fe fi igbagbo re han ninu adura kekere yi i ti o jewo ese re, ti o si ngba idarijin Re ati ti o nri igbagbo re sinu Kristi fun igbala re.
Bi o ba sese ni gbekele ninu Kristi, o nilo lati mo siwaju si I nipa igbe aiye re tuntun ati bi o se le rin pelu Oluwa. A da a laba wipe ki bere lati ma a keko ni adiresi yi ABCs for Christian Growth www.bible.org Awon eko wonyi yio mu ni sisentele ni eredi ati okodoro otito oro Olorun. Ewe, yio si ran o lowo lati ni ipile ti ni agbara fun igbagbo re ninu Kristi.